27/06/2020
Ojo Gbogbo la nse Oore, A o mo Ojo Esan:
Iya Alakara kan wa, Owo (Trade) Akara yi lo nse; O si ko Ile meji, O tun ra motor n'idi ise akara dindin yi.
Awon eniyan maa nto (line up) lati ra akara Iya yi ni; bi Oja (market) ni Idi Akara yi...
Alanganna (madman) kan ma nwa si odo Iya yii. Ni gbogbo araaro loma nwa, ti o ba si ti de, "Dami lohun" ni nkan ti o ma nso fun Iya alakara yi. Iya Alakara yi a si fun ni Akara aadota naira pelu Eko aadota naira. Alanganna yi A si ba tire lo. (Bo se ma nwa ni lojoojumo ni yen)
Ni ojo kan; Were yi ko tete de, Iya Alakara yi si ti setan lati ma lo, Iya Alakara yi wa nfo awon agbada (rrr) idinkara re l'owo; sugbon o ti fi Akara ati Eko Alanganna pamo sibi kan.
Ni ojiji ni Alanganna yi pe Iya Alakara yi ni isoda t**i pe ki Iya Alakara wa. Iya Alakara yi nwope Alanganna tun fe ki ohun soda t**i wa fun ni Akara ati Eko re.... Iya Alakara wa so fun pe k'owa gba onje re, pe ohun ti ba di sile, ohun si fe maa lo s'ile... Alanganna yi tenumo mo pe ki Iya Alakara soda t**i wa ba ohun. Iya Alakara ba gbe ounje lo fun Alanganna ni isoda t**i kole je ki ohun lo si ile lasiko...
Bi Iya Alakara yi ti de odo Alanganna yi ni Alanganna so fun Iya alakara yi pe: "OJO GBOGBO LA NS'ORE, A O MO OJO ESAN"
Alanganna yi so oro yi ni aimoye igba, sugbon ko ye Iya alakara yi rara...
Nibi ti won ti nse eleyi lowo ni Igi Araba ti Iya Alakara maa njoko si labe dede wo ni ojiji...
Gbogbo ara adugbo ba f'igbe ta pe Iya Alakara ti ku ooo, Eero tu jade lati wa wo ohun to sele, sugbon si iyalenu won: Iya Alakara ba soda t**i wa bawon pe: "Emi ree o, Mi O ku o" Gbogbo awon eniyan ba n salo pe: "Oku Iya Alakara lo yoju s'awon".
Iya Alakara wa bere si ni sunkun; O si ndupe lowo Olodumare fun yiyo ninu ewu Iku ojiji yi...
Eko:
Gbogbo Oore to nse yen o gbe ooo,... Esan nbo ni ojo ti O ni r'okan rara.... Soresore ma sore nso, Maje ko su E,... Awon kan nwo O fun iranlowo,...
Ma woo pe wahala won po,...
A gbe O kale lati pa awon Eda kan l'erin, Ki won ri Ayo lati odo E ni,...
Esan nbo fun E,...
Maje ko su E,...
Nitoripe, "Sore Sore, O mo Ojo Esan"*
Eni toba nsore Ara e lo nse fun l'ona Kan tabi Ekeji
"Ojo Gbogbo la nse Oore, A o Mojo Esan"